1 Samuel 28:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lojúkan náà ni Ṣọ́ọ̀lù ṣubú lulẹ̀ gbalaja ní bí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà t'ọ̀sán t'òru.