1 Samuel 28:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé, “Èmi kì yóò jẹun.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rọ̀ ọ́. Ó sì dide kúrò ni ilẹ̀, ó sì jókòó lorí àkéte.