1 Samuel 28:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rámà ní ìlú rẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.