1 Samuel 28:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”