1 Samuel 28:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé “Wò ó, ìwọ sáà mọ ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ṣe, bí òun ti gé àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èé ha ṣe tí ìwọ dẹ́kùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”