1 Samuel 29:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN Filistini si ko gbogbo ogun wọn jọ si Afeki: Israeli si do ni ibi isun omi ti o wà ni Jesreeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Fílístínì sì kó gbogbo ogun wọn jọ sí Áfékì: Ísírẹ́lì sì dó ni ibi ìsun omi tí ó wà ní Jésírélì.