1 Samuel 29:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?” Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ijoye Filistini si bere wipe, Kini awọn Heberu nṣe nihinyi? Akiṣi si wi fun awọn ijoye Filistini pe, Dafidi kọ yi, iranṣẹ Saulu ọba Israeli, ti o wà lọdọ mi lati ọjọ wọnyi tabi lati ọdun wọnyi, emi ko iti ri iṣiṣe kan li ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ ti o ti de ọdọ mi titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjòyé Fílístínì sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Hébérù ń ṣe nìhìn-ín yìí?” Ákíṣì sì wí fún àwọn ìjòyè Fílístínì pé “Dáfídì kọ yìí, ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”