1 Samuel 29:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ijoye Filistini si binu si i; awọn ijoye Filistini si wi fun u pe, jẹ ki ọkunrin yi pada ki o si lọ si ipò rẹ̀ ti o fi fun u, ki o má si jẹ ki o ba wa sọkalẹ lọ si ogun, ki o má ba jasi ọta fun wa li ogun; Kini on o fi ba oluwa rẹ̀ laja, ori awọn enia wọnyi kọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjòyé Fílístínì sì bínú sí i; àwọn ìjòyé Fílístínì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipó rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀ta fún wa ni ogun; Kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́?