1 Samuel 29:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.