1 Samuel 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú OLÚWA ní abẹ́ Élì. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ OLÚWA ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.