1 Samuel 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo ti sọ fún un pé n óo jẹ ìdílé rẹ̀ níyà títí lae, nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣe nǹkan burúkú sí mi. Eli mọ̀ pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lẹ́kun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ̀, nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.