1 Samuel 3:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samuẹli dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó dìde, ó ṣí gbogbo ìlẹ̀kùn ilé OLUWA, ṣugbọn ẹ̀rù ń bà á láti sọ ìran tí ó rí fún Eli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli dubulẹ titi di owurọ, o si ṣi ilẹkun ile OLUWA. Samueli si bẹru lati rò ifihan na fun Eli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Élì.