1 Samuel 3:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Kili ohun na ti Oluwa sọ fun ọ? emi bẹ ọ máṣe pa a mọ fun mi: ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si ọ, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ ba pa ohun kan mọ fun mi ninu gbogbo ohun ti o sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Élì béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí OLÚWA mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.”