1 Samuel 3:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli bá sọ gbogbo rẹ̀ patapata, kò fi nǹkankan pamọ́ fún un. Eli dáhùn pé, “OLUWA ni, jẹ́ kí ó ṣe bí ó bá ti tọ́ lójú rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si rò gbogbo ọ̀rọ na fun u, kò si pa ohun kan mọ fun u. O si wipe, Oluwa ni: jẹ ki o ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Élì wí pé, “Òun ni OLÚWA; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”