1 Samuel 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si tun Samueli pè lẹ̃kẹta. O si dide tọ Eli lọ, o si wipe, Emi nĩ; nitori iwọ pè mi. Eli, si mọ̀ pe, Oluwa li o npe ọmọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA pe Sámúẹ́lì ní ìgbà kẹ́tà, Sámúẹ́lì sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì ó sì wí pé, “Èmi nì yí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Élì wá mọ̀ pé OLÚWA ni ó ń pe ọmọ náà.