1 Samuel 30:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?” Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?” Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Éjíbítì ni èmi, ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Ámálékì. OLÚWA mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ijọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn.