1 Samuel 30:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?” Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?” Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.”