1 Samuel 30:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ijọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irínwó ọmọkùnrin tí wọ́n gun ràkúnmí tí wọ́n sì sá.