1 Samuel 30:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Bélíálì nínú àwọn tí o bá Dáfídì lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”