1 Samuel 30:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si bọ̀ si Siklagi, o si rán ninu ikogun na si awọn agbà Juda, ati si awọn ọrẹ́ rẹ̀, o si wipe, Wõ, eyi li ẹ̀bun fun nyin, lati inu ikogun awọn ọta Oluwa wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì padà sí Síkílágì, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbà Júdà, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀ta OLÚWA wa.”