1 Samuel 30:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítori ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dáfídì mu ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀.