1 Samuel 30:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?” OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.”