1 Samuel 31:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Fílístínì sì bá Ísírẹ́lì jà: àwọn ọkùnrin Ísírẹlì sì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn tí ó fi ara pa sì ṣubú ní òkè Gílíbóà.