1 Samuel 31:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọkunrin alagbara si dide, nwọn si fi gbogbo oru na rìn, nwọn si gbe okú Saulu, ati okú awọn ọmọbibi rẹ̀ kuro lara odi Betṣani, nwọn si wá si Jabeṣi, nwọn si sun wọn nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Ṣọ́ọ̀lù, àti okú àwọn ọmọ bibi rẹ̀ kúrò lára odi Bétísánì, wọ́n sì wá sí Jábésì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.