1 Samuel 31:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Fílístínì sì ń lépa Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Fílístínì sì pa Jónátanì àti Ábínádábù, àti Mélíkísúà, àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù.