1 Samuel 31:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún ẹni tí o ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lù ú.