1 Samuel 31:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà lápa kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jódánì, rí pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá, àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fí ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Fílístínì sí wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.