1 Samuel 4:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀RỌ Samueli si wá si gbogbo Israeli: Israeli si jade lọ pade awọn Filistini lati jagun, nwọn do si eti Ebeneseri: awọn Filistini si do ni Afeki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì tọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá. Nísinsìnyìí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde láti lọ bá àwọn Fílístínì jà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pàgọ́ sí Ebenésérì àti àwọn Fílístínì ní Áfékì.