1 Samuel 4:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà àwọn Fílístínì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Ísírẹ́lì olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; Àwọn ará Ísírẹ́lì tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ (30,000).