1 Samuel 4:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin náà dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn ará Filistia. Wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wa, wọ́n pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ rẹ mejeeji pẹlu. Wọ́n sì gbé àpótí Ọlọrun lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Ísírẹ́lì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn ọmọ ogun náà sì kú lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí OLÚWA lọ”