1 Samuel 4:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọkunrin náà fẹnu kan àpótí Ọlọ́run, Eli ṣubú sẹ́yìn lórí àpótí tí ó jókòó lé ní ẹnu ọ̀nà, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti di arúgbó, ó sì sanra. Ogoji ọdún ni Eli fi ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí OLÚWA, Élì sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún.