1 Samuel 4:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iyawo Finehasi, ọmọ Eli, wà ninu oyún ní àkókò náà, ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ sì ti súnmọ́ etílé. Nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ, ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú, lẹsẹkẹsẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, tí ó sì bímọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Fínéhásì, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí OLÚWA lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà.