1 Samuel 4:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Filistini si tẹ itẹgun lati pade Israeli: nigbati nwọn pade ija, awọn Filistini si le Israeli: nwọn si pa iwọn ẹgbaji ọkunrin ni itẹgun ni papa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn Fílístínì mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Ísírẹ́lì, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Fílístínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì wọ́n pa ẹgbàájì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000).