1 Samuel 4:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti ń kú lọ, àwọn obinrin tí wọn ń gbẹ̀bí rẹ̀ wí fún un pé, “Ṣe ọkàn gírí, ọkunrin ni ọmọ tí o bí.” Ṣugbọn kò tilẹ̀ kọ ibi ara sí ohun tí wọ́n sọ, kò sì dá wọn lóhùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.