1 Samuel 4:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá sọ ọmọ náà ní Ikabodu, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀.” Nítorí pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọrun ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì pe ọmọ náà ní Íkábódù, wí pé, “Kò sí ògo fún Ísírẹ́lì mọ́” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀.