1 Samuel 4:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọmọ ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì béèrè pé, “Èéṣe ti OLÚWA fi mú kí àwọn Fílístínì ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA láti Ṣílò wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbàwá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wa.”