1 Samuel 4:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú OLÚWA wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì.