1 Samuel 4:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ jẹ́ alágbára Fílístínì, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Hébérù, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín: Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!”