1 Samuel 5:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n tún gbé àpótí Ọlọrun náà ranṣẹ sí ìlú Filistini mìíràn, tí wọn ń pè ní Ekironi. Ṣugbọn bí wọ́n ti gbé e dé Ekironi ni àwọn ará ìlú fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun Israẹli dé síhìn-ín, láti pa gbogbo wa run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ékírónì. Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ékírónì, àwọn ará Ékírónì fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.”