1 Samuel 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí Ọlọrun Israẹli pada sí ibi tí ẹ ti gbé e wá, kí ó má baà pa àwa ati ìdílé wá run.” Ìpayà ńlá ti bá gbogbo ìlú nítorí OLUWA ń jẹ wọ́n níyà gidigidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Fílístínì jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí àyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn.