1 Samuel 5:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ara Aṣdodu ji li owurọ ọjọ keji, kiye si i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa. Nwọn si gbe Dagoni, nwọn si tun fi i si ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Ásídódù jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dágónì ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLÚWA, wọ́n sì gbé Dágónì, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.