1 Samuel 5:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ji li owurọ̀ ọjọ keji, kiyesi i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa; ati ori Dagoni ati atẹlẹ ọwọ́ rẹ̀ mejeji ke kuro li oju ọ̀na; Dagoni ṣa li o kù fun ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dágónì sì wá, ó ṣubú ó dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.