1 Samuel 5:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọwọ́ OLÚWA wúwo lára àwọn ènìyàn Ásídódù àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú àrùn oníkókó.