1 Samuel 5:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?” Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Fílístínì jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí OLÚWA àwọn Ísírẹ́lì?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA àwọn Ísírẹ́lì lọ sí Gátì.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.