1 Samuel 5:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí àpótí Ọlọrun náà dé Gati, OLUWA jẹ ìlú náà níyà, ó mú kí gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún ati àgbà ati èwe wọn, ó sì mú ìpayà bá gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ OLÚWA sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn oníkókó.