1 Samuel 6:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà ṣe bí àwọn babalóòṣà ti wí. Wọ́n mú mààlúù meji tí wọn ń fún ọmọ lọ́mú lọ́wọ́, wọ́n so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ti àwọn ọmọ wọn mọ́lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin na si ṣe bẹ̃: nwọn si mu abo malu meji; ti nfi ọmu fun ọmọ, nwọn si dè wọn mọ kẹkẹ́ na, nwọn si se ọmọ wọn mọ ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dèé ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé.