1 Samuel 6:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn mààlúù yìí bá doríkọ ọ̀nà Beti Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà láì yà sọ́tùn-ún tabi sósì. Wọ́n ń ké bí wọ́n ti ń lọ. Àwọn ọba Filistini maraarun tẹ̀lé wọn títí dé odi Beti Ṣemeṣi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn abo malu na si lọ tàra si ọ̀na Betṣemeṣi, nwọn si nke bi nwọn ti nlọ li ọ̀na opopo, nwọn kò yà si ọtún tabi si osì; awọn ijoye Filistini tẹle wọn lọ si agbegbe Betṣemeṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Béti-Ṣémésì, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Fílístínì tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Bẹti-Sémésì.