1 Samuel 6:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará ìlú Beti ṣemeṣi ń kórè ọkà lọ́wọ́ ní àfonífojì náà, bí wọ́n ti gbójú sókè, wọ́n rí àpótí ẹ̀rí. Inú wọn dùn pupọ pupọ bí wọ́n ti rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Betṣemeṣi nkore alikama wọn li afonifoji: nwọn gbe oju wọn soke, nwọn si ri apoti na, nwọn si yọ̀ lati ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, àwọn ará Bẹti-Sémésì ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí OLÚWA, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀.