1 Samuel 6:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà dé ibi oko Joṣua, ará Beti Ṣemeṣi, ó dúró níbẹ̀. Àpáta ńlá kan wà níbẹ̀, àwọn eniyan náà bá gé igi tí wọ́n fi kan kẹ̀kẹ́ ẹrù náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n pa mààlúù mejeeji, wọ́n sì fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kẹkẹ́ na si wọ inu oko Joṣua, ara Betṣemeṣi, o si duro nibẹ, ibi ti okuta nla kan gbe wà: nwọn la igi kẹkẹ na, nwọn si fi malu wọnni ru ẹbọ sisun si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kẹ̀kẹ̀ ẹrù wá sí pápá Jóṣúà ti Bẹti-Sémésì, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rúbọ sísun sí OLÚWA.