1 Samuel 6:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi bá gbé àpótí OLUWA náà, ati àpótí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà, wọ́n gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, ati oríṣìíríṣìí ẹbọ mìíràn sí OLUWA ní ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Lefi si sọ apoti Oluwa na kalẹ, ati apoti ti o wà pẹlu rẹ̀, nibiti ohun elo wura wọnni gbe wà, nwọn si fi le ori okuta nla na: awọn ọkunrin Betṣemeṣi si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ si Oluwa li ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Léfì gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA wá sí ìṣàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Bẹti-Sémésì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí OLÚWA.